57 Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu:
58 O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u.
59 Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i,
60 O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ.
61 Maria Magdalene si wà nibẹ̀, ati Maria keji, nwọn joko dojukọ ibojì na.
62 Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu,
63 Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde.