7 Nwọn si gbìmọ, nwọn si fi rà ilẹ amọ̀koko, lati ma sinkú awọn alejò ninu rẹ̀.
8 Nitorina li a ṣe npè ilẹ na ni Ilẹ ẹ̀jẹ, titi di ọjọ oni.
9 Nigbana li eyi ti Jeremiah wolĩ sọ wá ṣẹ, pe, Nwọn si mu ọgbọ̀n owo fadaka na, iye owo ẹniti a diyele, ẹniti awọn ọmọ Israeli diyele;
10 Nwọn si fi rà ilẹ, amọ̀koko, gẹgẹ bi Oluwa ti làna silẹ fun mi.
11 Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i.
12 Nigbati a si nkà si i lọrùn lati ọwọ́ awọn olori alufa, ati awọn àgbãgba wá, on kò dahùn kan.
13 Nigbana ni Pilatu wi fun u pe, Iwọ ko gbọ́ ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ?