1 NI ijọ wọnni ni Johanu Baptisti wá, o nwasu ni ijù Judea,
2 O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.
3 Nitori eyi li ẹniti woli Isaiah sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju-ọ̀na rẹ̀ tọ́.
4 Aṣọ Johanu na si jẹ ti irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ si ẹ̀gbẹ rẹ̀; onjẹ rẹ̀ li ẽṣú ati oyin ìgan.
5 Nigbana li awọn ara Jerusalemu, ati gbogbo Judea, ati gbogbo ẹkùn apa Jordani yiká jade tọ̀ ọ wá,