23 Nitorina bi iwọ ba nmu ẹ̀bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ,
24 Fi ẹ̀bun rẹ silẹ nibẹ̀ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ́ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn ẹ̀bun rẹ.
25 Ba ọtà rẹ rẹ́ kánkan nigbati iwọ wà li ọ̀na pẹlu rẹ̀; ki ọtá rẹ ki o má ba fi ọ le onidajọ lọwọ, onidajọ a si fi ọ le ẹ̀ṣọ lọwọ, a si gbè ọ sọ sinu tubu.
26 Lõtọ ni mo wi fun ọ, Iwọ kì yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.
27 Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga.
28 Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀.
29 Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi.