1 Ẹ máṣe dani li ẹjọ, ki a ma bà da nyin li ẹjọ.
2 Nitori irú idajọ ti ẹnyin ba ṣe, on ni a o si ṣe fun nyin; irú òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o si fi wọ̀n fun nyin.
3 Etiṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ ko kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ?
4 Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ.