11 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀?
12 Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli.
13 Ẹ ba ẹnu-ọ̀na hihá wọle; gbòro li ẹnu-ọ̀na na, ati onibú li oju ọ̀na na ti o lọ si ibi iparun; òpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ̀ wọle.
14 Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i.
15 Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu.
16 Eso wọn li ẹnyin o fi mọ̀ wọn. Enia a mã ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹ̀wọn?
17 Gẹgẹ bẹ̃ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu.