5 Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.
6 Ẹ máṣe fi ohun mimọ́ fun ajá, ki ẹ má si ṣe sọ ọṣọ́ nyin siwaju ẹlẹdẹ, ki nwọn má ba fi ẹsẹ tẹ̀ wọn mọlẹ, nwọn a si yipada ẹ̀wẹ, nwọn a si bù nyin ṣán.
7 Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin.
8 Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun.
9 Tabi ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rẹ̀ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u?
10 Tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò?
11 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀?