1 Ọba 15:17-23 BMY

17 Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì sì gòkè lọ sí Júdà, ó sì kọ́ Rámà láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Áṣà ọba lọ.

18 Nígbà náà ni Áṣà mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé Olúwa àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Bẹni-Hádádì ọmọ Tábírímónì, ọmọ Hésíónì ọba Síríà tí ó ń gbé ní Dámásíkù.

19 Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrin èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrin bàbá mi àti bàbá rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Bááṣà, ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”

20 Bẹni-Hádádì gba ti Áṣà ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Ísírẹ́lì. Ó sì ṣẹ́gun Íjónì, Dánì àti Abeli-Bẹti-Máákà, àti gbogbo Kénérótì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náfútalì.

21 Nígbà tí Bááṣà sì gbọ́ èyí, ó sì síwọ́ kíkọ́ Rámà, ó sì lọ kúrò sí Tírísà.

22 Nígbà náà ni Áṣà ọba kéde ká gbogbo Júdà, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta àti igi tí Bááṣà ń lò kúrò ní Rámà. Áṣà ọba sì fi wọ́n kọ́ Gébà ti Bẹ́ńjámínì àti Mísípà.

23 Níti ìyókù gbogbo ìṣe Áṣà, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, àrùn ṣe é ní ẹṣẹ̀ rẹ̀.