4 Ọba Éjíbítì sì mú Élíákímù, arákùnrin Jehóáhásì, jẹ ọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ Eliákímù padà sí Jéhóíákíámù, ṣùgbọ́n Nékò mú arákùnrin Eliákímù, Jehóáhásì ó sì gbé e lórí Éjíbítì.
5 Jéhóíákímù sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
6 Nebukadínésárì ọba Bábílónì sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú-un lọ sí Bábílónì.
7 Nebukadínésárì pẹ̀lú mú-un lọ sí Bábílónì, ohun èlò láti ilé Olúwa, ó sì mú wọn lọ sí ààfin tirẹ̀ níbẹ̀.
8 Ìyòókù isẹ́ ìjọba Jéhóíákíámù, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà. Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
9 Jehóiakínì sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún (18) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta àti ijọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa.
10 Ní àmọ́dún, ọba Nebukadínsárì ránsẹ́ síi ó sì mú-un wá sí Bábílónì, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé Olúwa, ó sì mú arákùnrin Jehóíákínì, Sedekíà, jọba lórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù.