2 Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Jéhóádínì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.
3 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dáfídì baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ́lé àpẹrẹ baba a rẹ̀ Jóásì.
4 Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.
5 Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọin-gbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.
6 Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mósè níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé: “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
7 Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ará Édómù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ iyọ̀, ó sì fi agbára mú Ṣélà nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jókítélì, orúkọ tí ó ní títí di òní.
8 Nígbà náà, Ámásáyà rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jóásì ọmọ Jéhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìpèlẹ́jọ́ “Wá, í bá mi lójúkorojú.”