2 Ọba 16:11-17 BMY

11 Úráyà àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Áhásì ọba fi ránṣẹ́ síi láti Dámásíkù; bẹ́ẹ̀ ni Úráyà àlùfàá ṣe é dé ìpadàbọ̀ Áhásì ọba láti Dámásíkù.

12 Nígbà tí ọba sì ti Dámásíkù dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rúbọ lórí rẹ̀.

13 Ó sì ṣun ẹbọ ọrẹ-ṣíṣun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun-mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n èjẹ̀ ọrẹ-àlàáfíà rẹ̀ sí ará pẹpẹ náà.

14 Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárin méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.

15 Áhásì ọba sì pàṣẹ fún Úráyà àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa ṣun ọrẹ-ṣíṣun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jijẹ alaalẹ́, àti ẹbọ ṣíṣun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ ṣíṣun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ọrẹ-sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn: ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.”

16 Báyìí ni Úráyà àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Áhásì ọba pa láṣẹ.

17 Áhásì ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó sí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada nlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́.