2 Ọba 16:2-8 BMY

2 Ẹni ogún ọdún ni Áhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ó sì jọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jérúsálẹ́mù, kò si ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀.

3 Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísíráẹ́lì, nítòótọ́, ó sì mú kí ọmọ rẹ̀ ó kọjá láàrin iná, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ ìrírà àwọn aláìkọlà, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísíráẹ́lì.

4 Ó sì rúbọ, ó sì ṣun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5 Nígbà náà ni Résínì ọba Ṣíríà àti Pẹ́kà ọmọ Rèmálíà ọba Ísíráẹ́lì gòkè wá sí Jérúsálẹ́mù láti jagun: wọ́n dó ti Áhásì, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.

6 Ní àkókò náà, Résínì Ọba Ṣíríà gba Élátì padà fún Ṣíríà, ó sì lé àwọn ènìyàn Júdà kúrò ní Élátì: àwọn ará Ṣíríà sì wá sí Élíátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.

7 Áhásì sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tigilati-Pílésérì ọba Ásíríà wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Síríà, àti lọ́wọ́ ọba Ísírẹ́lì tí ó díde sí mi.”

8 Áhásì sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúrà ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Ásíríà ní ọrẹ.