2 Ọba 17:24-30 BMY

24 Ọba Ásíríà mú àwọn ènìyàn láti Bábílónì, Kútà, Áfà, Hámátì àti Ṣéfáfáímù wọ́n sì dúró ní ìlú Ṣamáríà láti rọ́pò àwọn ará Ísírẹ́lì. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.

25 Nígbà tí wọ́n gbé bẹ́ ẹ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù Olúwa, Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárin wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn.

26 Wọ́n sì sọ fún ọba Ásíríà pé: “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Ṣamáríà kò mọ ohun tí Olúwa ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárin wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”

27 Nígbà náà ọba Ásíríà pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Ṣamáríà lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí Olúwa ilẹ̀ náà béèrè.”

28 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samáríà wá gbé ní Bétélì ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

29 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀ èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Ṣamáríà ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì.

30 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin láti Bábílónì ṣe àgọ́ àwọn wúndíá, àwọn ọkùnrin láti Kútì ṣe Négálì, àti àwọn ènìyàn láti Hámátì ṣe Áṣímà;