34 Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Árípádì gbé wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣérárifáímù, Hẹ́nà àti ífà gbé wà? Wọ́n ha gba Ṣámáríà kúrò lọ́wọ́ mi bí?
35 Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà ilẹ̀ yìí tí ó ti gbìyànjú láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa yóò ṣe gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”
36 Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn náà dákẹ́ síbẹ̀ wọn kò sì sọ ohunkóhun, láti fi fèsì, nítorí ọba ti paláṣẹ, “Ẹ má ṣe dáa lóhùn.”
37 Nígbà náà Élíákímù ọmọ Hílíkíyà olùtọ́jú ààfin, Séríbù akọ̀wé àti Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ránsẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Héṣékíáyà, pẹ̀lú aṣọ wọn yíya, ó sì wí fún un ohun tí olùdárí pápá ti sọ.