6 Àìṣáyà wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Áṣíríà ti sọ̀rọ̀ òdì sí mi.
7 Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gée lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”
8 Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Áṣíríà ti kúrò lákìsì ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Líbíńà jà.
9 Nísinsìn yìí Ṣenakéríbù sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tíránákà, ọba Etiópíà ti Éjíbítì wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán onísẹ́ sí Héṣékíáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé:
10 “Sọ fún Héṣékíáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí o gbékalẹ̀ kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jérúsálẹ́mù a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Ásíríà.’
11 Lọ́ọ̀tọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Ásíríà tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátapáta. Ìwọ yóò sì gbàlà?
12 Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn babańlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gósánì, Háránì Réṣéfù àti gbogbo ènìyàn Édẹ́nì tí wọ́n wà ní Télásárì?