10 Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣáfánì kà lára rẹ̀ níwájú ọba.
11 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.
12 Ó pa àsẹ yìí fún Áhíkámù àlùfáà, Hílíkíyà ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Míkáyà, àti Ṣáfánì akọ̀wé àti Aṣahíáyà ìránṣẹ́ ọba.
13 “Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Júdà nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Gíga ni ìbínú Olúwa tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.”
14 Hílíkíyà àlùfáà, Áhíkámù àti Ákíbórì pẹ̀lú Ṣáfánì, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti lọ bá a sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ aya Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háríhásì alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ní ìdà kejì.
15 Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sími,
16 ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Júdà ti kà.