2 Ọba 22:14-20 BMY

14 Hílíkíyà àlùfáà, Áhíkámù àti Ákíbórì pẹ̀lú Ṣáfánì, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti lọ bá a sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ aya Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háríhásì alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ní ìdà kejì.

15 Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sími,

16 ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò mú ibi wá sí ibí àti àwọn ènìyàn rẹ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé tí ọba Júdà ti kà.

17 Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì tún ṣun tùràrí fún ọlọ́run mìíràn. Wọ́n sì mú mi bínú nípa gbogbo àwọn òrìṣà tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn dá. Ìbínú mi yóò ru sí ibí yìí, kì yóò sì rọlẹ̀’

18 Sọ fún ọba Júdà tí ó rán yín láti bèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa ọ̀rọ̀ wọ̀n-ọn-nì tí ìwọ ti gbọ́.

19 Nítorí tí ọkàn rẹ rọ̀, tí ìwọ sì ti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa, nígbà tí ìwọ gbọ́ èyí tí mo sọ sí ibí yìí àti sí àwọn ènìyàn rẹ pé wọn yóò di ahoro àti ẹni ègún tí ìwọ sì fa aṣọ ọ̀ rẹ ya pẹ̀lú níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ, ni Olúwa wí.

20 Nítorí náà èmi yóò kó ọ jọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baba à rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kì yóò rí gbogbo àwọn ibi tí èmi yóò mú wá bá ibí yìí.’ ”Bẹ́ẹ̀ wọ́n mú èsì rẹ̀ padà tọ ọba wá.