2 Ọba 22:9-15 BMY

9 Nígbà náà, Ṣáfánì akọ̀wé lọ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìjòyè rẹ ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa. Èmi sì ti fi lé ọwọ́ àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ náà àti àwọn alábojútó nílé Olúwa.”

10 Nígbà náà Ṣáfánì akọ̀wé sọ fún ọba pé, “Hílíkíyà àlùfáà ti fún un ní ìwé kan.” Ṣáfánì kà lára rẹ̀ níwájú ọba.

11 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.

12 Ó pa àsẹ yìí fún Áhíkámù àlùfáà, Hílíkíyà ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Míkáyà, àti Ṣáfánì akọ̀wé àti Aṣahíáyà ìránṣẹ́ ọba.

13 “Lọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi àti fún àwọn ènìyàn àti fún gbogbo Júdà nípa ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Gíga ni ìbínú Olúwa tí ó ń jó sí wa nítorí àwọn baba wa kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí; wọn kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ níbẹ̀ nípa wa.”

14 Hílíkíyà àlùfáà, Áhíkámù àti Ákíbórì pẹ̀lú Ṣáfánì, lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin Húlídà láti lọ bá a sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ aya Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háríhásì alábojútó ibi ìpa aṣọ mọ́ sí. Ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ní ìdà kejì.

15 Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Sọ fún ọkùnrin tí ó rán an yín sími,