3 Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Júdà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Mánásè àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe.
4 Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjìn.
5 Ní ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéhóíákímù, àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ọba Júdà?
6 Jéhóíákímù sùn pẹ̀lú baba rẹ̀, Jéhóíákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
7 Ọba Éjíbítì kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Bábílónì ti gba gbogbo agbégbé rẹ̀ láti odò Éjíbítì lọ sí odò Éúférátè.
8 Jéhóíákínì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a sì máa jẹ́ Néhúṣítà ọmọbìnrin Élínátanì; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.
9 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.