4 Nígbà náà odi ìlú náà sì fón ká, gbogbo àwọn ọmọ ogun sá lọ ní òru láti ẹnu ọ̀nà bodè láàrin ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, lára àwọn ará Bábílónì wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sá lọ sí ìkọjá Árábù.
5 Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará kalídíà sì lépa ọba, wọ́n sì lée bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jéríkò. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,
6 Wọ́n sì mú un wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbílà, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.
7 Wọ́n sì pa ọmọ Ṣédékáyà níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Bábílónì.
8 Ní ọjọ́ kèje ní oṣù karùn ún, ní ọdún ìkọkàndínlógún ti Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebukadinéṣárì olórí ẹ̀sọ́ ti ọba ìjòyè ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù
9 ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé pàtàkì, ó jó wọn níná.
10 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì, lábẹ́ olórí ti ìjọba ẹ̀sọ́, wó ògiri tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká lulẹ̀.