11 Àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedì-Édómù ará Gátì ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedì-Édómù, àti gbogbo ilé rẹ̀.
12 A sì rò fún Dáfídì ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedì-Édómù, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dáfídì sì lọ, ó sì mú àpótí-ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedì-Édómù wá sí ìlú Dáfídì pẹ̀lú ayọ̀.
13 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí-ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rúbọ.
14 Dáfídì sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dáfídì sì wọ éfódù ọ̀gbọ̀.
15 Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.
16 Bí àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dáfídì wá; Mikali ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dáfídì ọba ń fò sòkè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.
17 Wọ́n sì mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrin àgọ́ náà tí Dáfídì pa fún un: Dáfídì sì rubọ́ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa.