10 Olúwa Ọlọ́run yín ti sọ yín di púpọ̀ lónìí, ẹ̀yin sì ti pọ̀ bí ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run.
11 Kí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín sọ yín di púpọ̀ ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún sí i, kí ó sì bùkún un yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.
12 Báwo ni èmi nìkan ṣe lè má a ru àjàgà àti ìsòro yín àti èdè àìyedè yín?
13 Ẹ yan àwọn ọlọgbọ́n, olóye àti àwọn ẹni àpọ́nlé, láti inú ẹ̀yà yín kọ̀ọ̀kan, èmi yóò sì fi wọ́n ṣe olórí yín.”
14 Ẹ̀yin sì dá mi lóhùn wí pé, “Ohun tí ìwọ ti gbérò láti ṣe n nì dára.”
15 Bẹ́ẹ̀ ni mo yan àwọn aṣáájú ẹ̀yà yín, àwọn ọlọgbọ́n àti ẹni àpọ́nlé láti ṣe àkóso lórí yín: gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹgbẹgbẹ̀rún, ọgọgọ́rùn-ún, àràádọ́ta, ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá àti gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ẹ̀yà.
16 Mo sì kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ yín nígbà náà pé: Ẹ gbọ́ èdè àìyedè tí ó wà láàrin àwọn ènìyàn an yín kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ òdodo, bóyá ẹjọ́ tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin Ísírẹ́lì sí Ísírẹ́lì ni tàbí láàrin Ísírẹ́lì kan sí àlejò.