1 Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu un mi.
2 Jẹ́kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,kí awọn ọ̀rọ̀ mi máa ṣọ̀kalẹ̀ bí ìrì,bí òjò winiwini sára ewéko túntún,bí ọ̀wàrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.
3 Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa,Áà, ẹ yìn títóbi Ọlọ́run wa!
4 Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.Ọlọ́run olótìítọ́ tí kò ṣe àsìṣe kan,Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
5 Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apákan tí ó sì doríkodò.
6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,Áà ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?
7 Rántí ìgbà láéláé;wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,àwọn àgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.
8 Nígbà tí atóbijù fi ogún àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn,nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàngẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.
9 Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,Jákọ́bù ni ìpín ìní i rẹ̀.
10 Ní ihà ni ó ti rí i,ní ihà níbi tí ẹranko kò sí.Ó yíká, ó sì tọ́jú u rẹ̀,ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.
11 Bí idì ti íru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ńrábàbà sórí ọmọ rẹ̀,tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sìgbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.
12 Olúwa samọ̀nà;kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.
13 Ó mú gun ibi gíga ayéó sì fi èṣo oko bọ́ ọ.Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,àti òróró láti inú akọ òkúta wá,
14 Pẹ̀lú u wàràǹkàsì àti wàrà àgùntànàti ti àgbò ẹranàti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́,pẹ̀lú àgbò irú u ti Báṣánìtí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èṣo-àjàrà, àní àti wáìnì.
15 Jéṣúrúnì sanra tán ó sì tàpá;ìwọ ṣanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọo sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.
16 Wọ́n sì fi jowú pẹ̀lú ọlọ́run àjèjì i wọnwọ́n sì mú un bínú pẹ̀lú àwọn òrìṣà a wọn.
17 Wọ́n rúbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó sẹ̀sẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.
18 Ìwọ kò rántí Àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.
19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ.
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.
21 Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè.
22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.
24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.
25 Idà ní òde,àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù.Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá,ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.
26 Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúró nínú àwọn ènìyàn,
27 nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀ta,kí àwọn ọ̀ta a wọn kí ó mába à wí pé, ‘Ọwọ́ ọ wa lékè ni;kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”
28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìmọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú un wọn.
29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọnkí wọn ròbí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí!
30 Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàaàrún sá,bí kò ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n,bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?
31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí Àpáta wa,àní àwọn ọ̀ta wa tìkálára wọn ń ṣe onídàájọ́.
32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sódómùàti ti ìgbẹ́ ẹ Gòmórà.Èṣo àjàrà wọn kún fún oró,Ìdì wọn korò.
33 Ọtí wáìnì ni ìwọ ti dírágónì,àti oró mímú ti pamọ́lẹ̀.
34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́èmi kò sì fi èdìdì dìí ní ìṣúra à mi?
35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san; Èmi yóò san án fún wọnní àkókò tí ẹ̀sẹ̀ wọn yóò yọ;ọjọ́ ìdàmú wọn sún mọ́ etíléohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”
36 Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tántí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.
37 Yóò wí pé: “Òrìṣà a wọn dà báyìí,àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,
38 ọlọ́run tí ó jẹ ara ẹbọ wọntí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!
39 “Wòó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.
40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé:Èmi ti wà láàyè títí láé,
41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán miàti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá miÈmi kò sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.
42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:Ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,orí àwọn asáájú ọlá.”
43 Ẹyọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta a rẹ̀yóò sì se ètùtù fún ilẹ̀ rẹ̀ àti ènìyàn.
44 Móṣè wà pẹ̀lú u Jóṣúà ọmọ Núnì ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn.
45 Nígbà tí Móṣè parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Ísírẹ́lì.
46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti ṣọ láàrin yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́ran àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
47 Wọn kì í se ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jọ́dánì lọ láti gbà.”
48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Móṣè pé,
49 “Gòkè lọ sí Ábárímù sí òkè Nébò ní Móábù, tí ó kọjú sí Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénánì ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Isírẹ́lì, bí ìní i wọn.
50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Árónì ti kú ní orí òkè Hórù tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀.
51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibi omi Móríbà Kádésì ní ihà Ṣínì àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrin àwọn ọmọ Isírẹ́lì.
52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”