Deutarónómì 16 BMY

Àjọ Ìrékọjá.

1 Ẹ kíyèsí oṣù Ábíbù, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Ábíbù yìí ni ó mú un yín jáde ní Éjíbítì lóru.

2 Ẹ fi ẹran kan rúbọ bí ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀.

3 Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Éjíbítì: kí ẹ báà lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Éjíbítì ní gbogbo ọjọ́ ayé e yín.

4 Kí a má ṣe rí ìwúkàrà ní ọ̀dọ̀ ọ yín nínú ilẹ̀ ẹ yín fún ọjọ́ méje. Ẹ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan sẹ́kù nínú ẹran tí ẹ ó fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kéjì.

5 Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín

6 bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

7 Ẹ ṣun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.

8 Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fí jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ kéje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

Ayẹyẹ Àwọn Ọ̀ṣẹ̀.

9 Ka ọ̀ṣẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà.

10 Nígbà náà ni kí ẹ se àjọ̀dún ọ̀ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèṣè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.

11 Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrú u yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn Léfì tí ó wà ní ìlú u yín, àti àwọn àlejò, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárin yín.

12 Ẹ rántí pé ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.

Ayẹyẹ Àgọ́ Ìpàdé.

13 Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán.

14 Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Léfì, àwọn àjòjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín.

15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi se ayẹyẹ fún Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.

16 Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni gbogbo àwọn ènìyàn an yín gbọdọ̀ farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn. Níbi àpèjẹ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀ṣẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ wá ṣíwájú Olúwa lọ́wọ́ òfo.

17 Olúkúlùkù u yín gbọdọ̀ mú ẹ̀bùn wá bí Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún fún un tó.

Àwọn Adájọ́.

18 Ẹ yan àwọn adájọ́ àti àwọn olóyè fún ẹ̀yà a yín kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ìlú tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, wọ́n sì gbọdọ̀ máa fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.

19 Ẹ má ṣe yí ẹjọ́ po, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojúṣàájú. Ẹ má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọgbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́.

20 Ẹ tẹ̀lé ìdájọ́ òtítọ́ àní ìdájọ́ òtítọ́ nìkan, kí ẹ báà lè gbé kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín.

Sísin Ọlọ́run Mìíràn.

21 Ẹ má ṣe ri òpó òrìṣà áṣérà ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tí ẹ ti mọ fún Olúwa Ọlọ́run yín.

22 Ẹ kò gbọdọ̀ gbé òkúta òrìṣà gbígbẹ́ kan kalẹ̀ fún ara yín, nítorí èyí ni Olúwa Ọlọ́run yín kórìíra.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34