1 Bí wòlíì tàbí aláṣọtẹ́lẹ̀ nípa àlá lílá bá farahàn láàrin yín, tí ó sì ń kéde iṣẹ́ àmì tàbí iṣẹ́ ìyanu,
2 bí iṣẹ́ àmí tàbí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ṣẹ tí òun sì wí pé, “ẹ wá ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀ rí) “kí ẹ sì jẹ́ kí a máa sìn wọ́n,”
3 ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ tàbí àlá náà, Olúwa Ọlọ́run yín ń dán an yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn an yín.
4 Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀: ẹ sìn ín, kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin.
5 Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrin yín.
6 Bí arákùnrin tìrẹ gan-an ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin, aya tí o fẹ́ràn jù, tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bá tàn ọ́ jẹ níkọ̀kọ̀ wí pé jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn, (ọlọ́run tí ìwọ tàbí baba rẹ kò mọ̀
7 ọlọ́run (òrìṣà) àwọn tí ó wà láyìíka yín, yálà wọ́n jìnnà tàbí wọ́n wà nítòsí, láti òpin ilẹ̀ kan dé òmíràn.)
8 Má ṣe fetí sí i, má sì dá sí i, má ṣe dáàbò bò ó.
9 O gbọdọ̀ pa á ni. Ìwọ gan an ni kí o kọ́kọ́ gbé ọwọ́ rẹ lé e tàbí pa á, lẹ́yìn náà kí gbogbo àwọn yóòkù ṣù bò ó láti pa á.
10 Sọ ọ́ ní òkúta pa nítorí pé ó gbìyànjú láti fà ọ́ kúrò lẹ́yìn Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó mú ọ jáde ti Éjíbítì wá kúrò ní oko ẹrú.
11 Gbogbo Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí yóò dán irú ibi bẹ́ẹ̀ wò mọ́.
12 Bí ẹ bá gbọ́ tí a sọ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ìlú u yín tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín láti máa gbé,
13 pé àwọn ènìyàn búburú, ti farahàn láàrin yín, tí ó sì ti mú kí àwọn ènìyàn ìlú wọn sìnà lọ, tí wọ́n wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sin ọlọ́run mìíràn,” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀.)
14 Kí ẹ wádìí, ẹ bèèrè, kí ẹ sì tọpinpin ọ̀rọ̀ náà dájúṣáká, bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni, tí ó sì hàn dájú pé ìwà ìríra yìí ti ṣẹlẹ̀ láàrin yín.
15 Gbogbo àwọn tí ó ń gbé ìlú náà ni kí ẹ fi idà run pátápátá. Ẹ run ún pátapáta, àti ènìyàn àti ẹran ọ̀sìn inú rẹ̀.
16 Ẹ kó gbogbo ìkógun ìlú náà, sí àárin gbogbo ènìyàn, kí ẹ ṣun ìlú náà àti gbogbo ìkógun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun sísun sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. Ó gbọdọ̀ wà ní píparun láéláé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tún-un kọ.
17 A kò gbọdọ̀ rí ọ̀kan nínú àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun wọ̀n-ọn-nì lọ́wọ́ ọ yín, kí Olúwa ba à le yípadà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀, yóò sì ṣàánú fún un yín, yóò sì bá a yín kẹ́dùn, yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i, bí ó ti fìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá yín.
18 Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí mo ń fún un yín lónìí yìí tí ẹ sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ̀.