Deutarónómì 11 BMY

Fẹ́ràn Olúwa Kí O Sì Gbọ́ Tirẹ̀

1 Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo.

2 Ẹ rántí lónìí pé kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀;

3 iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárin àwọn ará Éjíbítì: Sí Fáráò ọba Éjíbítì àti gbogbo orílẹ̀ èdè rẹ̀.

4 Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Éjíbítì, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́sin rẹ̀: bí ó se rì wọ́n sínú òkun pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátapáta títí di òní olónìí yìí.

5 Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní ihà, títí ẹ fi dé ìhín yìí,

6 ohun tí ó ṣe sí Dátanì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù, ẹ̀yà Rúbẹ́nì, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Ísírẹ́lì tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn.

7 Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.

8 Nítorí náà, ẹ kíyèsí gbogbo àṣẹ tí mo ń fún un yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá lọ.

9 Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn: ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.

10 Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Éjíbítì, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹṣẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bominrin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́.

11 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jọ́dánì kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run.

12 Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.

13 Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín:

14 nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró.

15 Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó.

16 Ẹ ṣọ́ra, kí a má bàá tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin Ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn.

17 Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má baà rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín.

18 Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ ọ yín, kí ẹ sì ṣo wọ́n mọ́ iwájú orí i yín.

19 Ẹ máa fí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.

20 Ẹ kọ wọ́n sí férémù ìlẹ̀kùn yín, àti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé e yín.

21 Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fifún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìṣàlẹ̀.

22 Bí ẹ bá farabalẹ̀ kíyèsí àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé: Láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìí mú ṣinṣin:

23 Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.

24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aṣálẹ̀ dé Lẹ́bánónì, àti láti odò Yúfúrátè dé òkun ìwọ̀ oòrùn.

25 Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.

26 Ẹ kíyèsí i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí:

27 ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.

28 Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tíì mọ̀.

29 Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín ba ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gérísímù, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ébálì.

30 Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jọ́dánì ní apá ìwọ̀ oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igbó igi Mórè ńlá, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kénánì, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbégbé Gígálì.

31 Ẹ ti ṣetan láti la Jọ́dánì kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀,

32 ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́ran sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34