1 Kí ẹnikẹ́ni tí a fọ́ ní kóró ẹpọ̀n nípa rírùn tàbí gígé má ṣe wọ inú ìjọ ènìyàn wá.
2 Kí ọmọ àlè má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹwàá.
3 Kí Ámónì tàbí Móábù tàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn má ṣe wọ ìpéjọ Olúwa, pàápàá títí dé ìran kẹ̀wàá.
4 Nítorí wọn kò fi àkàrà àti omi pàdé e yín lójú ọ̀nà nígbà tí ò ń bọ̀ láti Éjíbítì àti nítorí wọ́n gba ẹ̀yà iṣẹ́ láti fi ọ́ gégún Bálámù ọmọ Béórì ará a Pétórì ti Árámù Náháráímù.
5 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Bálámù ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.
6 Má ṣe wá ìpinnu ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú u wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láàyè.
7 Má ṣe kórìíra ará Édómù kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Má se kórìíra ará Éjíbítì, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àléjò ní ilẹ̀ rẹ̀.
8 Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.
9 Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀ta rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.
10 Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.
11 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.
12 Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.
13 Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.
14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrin àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀taà rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ ọ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrin yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ yín.
15 Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
16 Jẹ́ kí ó máa gbé láàrin rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyí ìlú tí ó bá mú. Má se ni í lára.
17 Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Ísírẹ́lì má ṣe padà di alágbérè ojúbọ òrìṣà.
18 O kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ korìíra àwọn méjèèjì.
19 Má ṣe ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.
20 O lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
21 Bí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ọ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.
22 Ṣùgbọ́n tí o bá fà ṣẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi.
23 Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá sọ jáde láti ẹnu rẹ, nítorí pé o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.
24 Bí o bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi ìkankan sínú agbọ̀n rẹ.
25 Bí o bá wọ inú oko ọkà aládùúgbò rẹ, o lè fi ọwọ́ rẹ ya sírì rẹ̀, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ki dòjé bọ ọkà tí ó dúró.