Deutarónómì 9 BMY

Kì í Se Nítorí Òdodo Ísírẹ́lì

1 Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì. Báyìí, ẹ ti gbáradì látí la Jọ́dánì kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńláńlá, tí odi wọn kan ọ̀run.

2 Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Ánákì ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Ánákì (Òmìrán)?”

3 Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ ó sì lé wọ́n jáde, ẹ ó sì run wọ́n kíákíá, bí Olúwa ti ṣèlérí fún un yín.

4 Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní Olúwa se mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò se lé wọn jáde níwájú u yín.

5 Kì í se nítorí òdodo yín, tàbí ìdúróṣinṣin ni ẹ ó fí wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.

6 Ṣùgbọ́n kí ó yé yín pé kì í ṣe nítorí òdodo yín ni Olúwa Ọlọ́run yín fi ń fún un yín ní ilẹ̀ rere náà, láti ní, nítorí pé alágídí ènìyàn ni ẹ jẹ́.

Ère Òrìṣà Wúrà

7 Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ ti mú Olúwa Ọlọ́run yín bínú ní ihà. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Éjíbítì ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa títí tí ẹ fi dé ìhín yìí.

8 Ní Hórébù ẹ mú kí Olúwa bínú, títí débi pé ó fẹ́ run yín.

9 Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba sílétì òkúta, sílétì májẹ̀mú ti Olúwa ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mumi.

10 Olúwa fún mi ní òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí.

11 Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, sílétì òkúta májẹ̀mú náà.

12 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìnín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Éjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kíá, nínú àṣẹ mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”

13 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé alágídí ènìyàn gbáà ni wọ́n.

14 Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀ jù wọ́n lọ.”

15 Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí okè náà wá, orí òkè tí o ń yọná. Àwọn sílétì májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.

16 Gbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín.

17 Bẹ́ẹ̀ ni mó ju síléètì méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.

18 Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru: Èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú Olúwa, tí ẹ sì ń mú u bínú.

19 Mo bẹ̀rù ìbínú àti ìrunú Olúwa, nítorí pé inú bí i sí i yín débi wí pé ó fẹ́ pa yín run. Ṣùgbọ́n Olúwa tún fetí sí mi lẹ́ẹ̀kàn síi.

20 Inú sì bí Olúwa sí Árónì láti pa á run, nígbà náà ni mo tún gbàdúrà fún Árónì náà.

21 Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́sẹ̀, àní ère òrìṣà màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn níṣàlẹ̀ òkè.

22 Ẹ̀yin tún mú Olúwa bínú ní Tábérà, Másà àti ní Kíbírò Hátafà.

23 Nígbà tí Olúwa ran an yín jáde ní Kadesi Báníyà, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.

24 Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ yín ni ẹ ti ń sọ̀tẹ̀ sí Olúwa.

25 Mo ti wólẹ̀ níwájú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí nítorí pé Olúwa sọ pé Òun yóò pa yín run.

26 Mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti ràpadà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Éjíbítì wá.

27 Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù. Fojú fo orí kunkun àwọn ènìyàn yìí, pẹ̀lú ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

28 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, ‘Torí pé Olúwa kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní ihà.’

29 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ ni wọ́n, ogún rẹ tí o ti fi ọwọ́ agbára rẹ àti nínà ọwọ́ rẹ mú jáde.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34