Deutarónómì 29 BMY

Ìsọdi Túntún Májẹ̀mú.

1 Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pa láṣẹ fún Mósè láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Móábù, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Hórébù,

2 Móṣè pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì sọ fún wọn wí pé:Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.

3 Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá.

4 Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí Olúwa kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ.

5 Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín sọ́nà ní ihà, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹṣẹ̀ rẹ.

6 O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.

7 Nígbà tí o dé ibí yìí, Ṣíhónì ọba Hésíbónì àti Ógù ọba Básánì jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a sẹ́gun wọn.

8 A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè bí ogún.

9 Rọra máa tẹ̀lé ìpinnu májẹ̀mú yìí, kí o lè ṣe rere nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.

10 Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: adarí ì rẹ àti olórí àwọn ọkùnrin, àwọn àgbààgbà rẹ àti àwọn olóyè àti gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Ísírẹ́lì,

11 pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi ì rẹ.

12 O dúró níhìn ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú ù rẹ lónìí yìí àti tí óun dè pẹ̀lú ìbúra,

13 láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù.

14 Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan

15 tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.

16 Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Éjíbítì àti bí a se kọjá láàrin àwọn orílẹ̀ èdè nílẹ̀ ibí yìí.

17 Ìwọ rí láàrin wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà.

18 Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrin yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àtí láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrin yín.

19 Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà lálàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú ìjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà

20 Olúwa kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjìí; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, Olúwa yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run.

21 Olúwa yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí.

22 Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àlejò tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn àrùn pẹ̀lú tí Olúwa mú bá ọ.

23 Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-òórùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè ṣo èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Ṣódómù àti Gòmórà, Ádímà àti Sébóíímù, tí Olúwa bì subú nínú ìbínú u rẹ̀, àti ìkannú rẹ̀.

24 Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò béèrè pé, “Kí ló dé tí Olúwa fi ṣe èyí sí ilẹ̀ yìí? Kí ni a lè mọ ooru ìbínú ńlá yìí sí?”

25 Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí: “Nítorí tí ènìyàn yìí kọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Éjíbítì.

26 Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì forí balẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn.

27 Nígbà náà ni ìbínú Olúwa ru sí ilẹ̀ wọn, débi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀.

28 Ní ìbínú àti ní ìkannú, àti ní ìrunú ńlá, Olúwa sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí.”

29 Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fi hàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34