Deutarónómì 4 BMY

Mósè Pàṣẹ Ìgbọràn

1 Gbọ́ Ísírẹ́lì, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín.

2 Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.

3 Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Báálí-Péórì. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Báálì ti Péórì kúrò ní àárin yín.

4 Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láàyè lónìí.

5 Ẹ kíyèsí i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run-ùn mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní.

6 Ẹ máa kíyèsí wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀ èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀ èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”

7 Orílẹ̀ èdè olókìkí wo ni Ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkugbà tí a bá ń képè é?

8 Orílẹ̀ èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

9 Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì sọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láàyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

10 Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Hórébù, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ ṣíwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”

11 Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí ẹ sì dúró ní ẹṣẹ̀ òkè náà, nígbà tí òkè náà yọná lala lọ sókè ọrun pẹ̀lú ìkúùkù ńlá, àti òkùnkùn biribiri.

12 Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárin iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.

13 Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí sílétì òkúta méjì.

14 Olúwa sọ fún mi nígbà tí ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lée, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ ìní yín lẹ́yìn tí ẹ bá la Jọ́dánì kọjá.

Èèwọ̀ Ni Ìbọ̀rìṣà Jẹ́

15 Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárin iná wá. Torí náà ẹ sọ́ra yín gidigidi,

16 kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin,

17 tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò lófuurufú,

18 tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi.

19 Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ débi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run.

20 Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ị́jíbítì, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

21 Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín.

22 Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdì kejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà.

23 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá: Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí.

24 Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.

25 Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́: Bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yòówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú.

26 Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jọ́dánì kọjá lọ láti gbà. Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátapáta.

27 Olúwa yóò fọ́n-ọn yín ká sí àárin àwọn ènìyàn náà, àwọn díẹ̀ nínú un yín ni yóò yè láàrin orílẹ̀ èdè tí Olúwa yóò fọ́n ọn yín sí.

28 Ẹ ó sì máa sin Ọlọ́run tí àwọn ènìyàn fi ọwọ́ ṣe: tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe, èyí tí kò le ríran, gbọ́rọ̀, jẹun tàbí gbọ́ òórùn.

29 Bí ẹ̀yin bá wá Olúwa Ọlọ́run yín láti bẹ̀ẹ́ ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín.

30 Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ Olúwa Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀.

31 Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.

Olúwa Ni Ọlọ́run

32 Ẹ bèèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ bèèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkì báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí?

33 Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè?

34 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀ èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína ọwọ́, tàbí nípa iṣẹ́ ipá àti agbára ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Éjíbítì ní ojú ẹ̀yin tìká ara yín?

35 A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀.

36 Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní aye, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárin iná wá,

37 torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láàyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Éjíbítì.

38 Láti lé àwọn orílẹ̀ èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.

39 Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ níhìn ín. Kò sí òmíràn mọ́.

40 Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.

Àwọn Ìlú Ààbò

41 Mósè sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì.

42 Níbi tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn le sálọ, bí ó bá ṣe pé ó ṣèèṣì pa aládúgbò rẹ̀ láìsí ìkùnsínú láàrin wọn. Òun le sálọ sí èyíkéyìí nínú ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, fún ìgbàlà ẹ̀mí ara rẹ̀.

43 Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: Bésérì ní òkè olórí títẹ́ tí ó wà ní aṣálẹ̀, fún àwọn ará Rúbẹ́nì; Rámótì ní Gílíádì fún àwọn ará Gádì àti Gólánì ní Básánì fún àwọn ará Mánásè.

Ìfáàrà Sí Òfin

44 Èyí ni òfin tí Mósè gbékalẹ̀ fún àwọn ará Ísírẹ́lì.

45 Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ ìlànà àti òfin tí Mósè fún wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Éjíbítì.

46 Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Bétí Péórì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì; ní ilẹ̀ Ṣíhónì, ọba àwọn Ámórì tí ó jọba Hésíbónì tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Éjíbítì bọ̀.

47 Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ógù ọba Básánì àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.

48 Ilẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti Áréórì ní etí odò Ánónì dé orí òkè Ṣíhónì (èyí ni Hámónì).

49 Àti gbogbo aginjù ní ìlà oòrùn Jọ́dánì títí dé òkun aginjù (òkun iyọ̀) ní ìṣàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34