Deutarónómì 6 BMY

Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ

1 Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí Olúwa Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsí i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jọ́dánì.

2 Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀.

3 Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́ran, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ.

4 Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ṣoṣo ni.

5 Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ.

6 Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ má a wà lóókan àyà yín.

7 Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.

8 Ẹ ṣo wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín.

9 Ẹ kọ wọ́n sára àwọn férémù ìlẹ̀kùn àwọn ilé yín àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde yín.

10 Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú ọ dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín: Fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù láti fi fún un yín, Ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ,

11 àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kàǹga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso ólífì tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n: Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó,

12 ẹ sọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Éjíbítì wá, kúrò ní oko ẹrú.

13 Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan.

14 Ẹ má ṣe tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká;

15 torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.

16 Ẹ má ṣe dán Olúwa Ọlọ́run yín wò bí ẹ ti ṣe ní Máṣà.

17 Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín.

18 Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín.

19 Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀ta yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí.

20 Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?”

21 Sọ fún un pé: “Ẹrú Fáráò ní ilẹ̀ Éjíbítì ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Éjíbítì.

22 Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Éjíbítì àti Fáráò, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀.

23 Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wa.

24 Olúwa pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ran sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, làti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó báà lè má a dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a se wà títí di òní.

25 Bí a bá sọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34