1 Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí ihà, a gba ọ̀nà òkun pupa, bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Séírì.
2 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé,
3 “Ẹ ti rìn yí agbégbé ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá.
4 Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Ísọ̀; àwọn ará Édómù tí ń gbé ní Séírì. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.
5 Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí o ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Séírì fún Ísọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.
6 Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”
7 Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín. Ó ti mójú tó ìrìnàjò yín nínú ihà ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogojì ọdún wọ̀nyí, débi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.
8 Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Ísọ̀ tí ń gbé ní Séírì. A yà kúrò ní ọ̀nà aginjù èyí tí ó wá láti Élátì àti Ésíóni-Gébérì, a sì rìn gba ọ̀nà ihà Móábù.
9 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Móábù bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi Árì fún àwọn ọmọ Lọ́tì bí i ìní.”
10 Àwọn Émímù ti gbé ibẹ̀ rí: Àwọn ènìyàn tó sígbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn Ánákì.
11 Gẹ́gẹ́ bí Ánákì àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará Ráfátì ṣùgbọ́n àwọn ará Móábù pè wọ́n ní Émímù.
12 Àwọn ará Hórì gbé ní Séírì kí àwọn ọmọ Ísọ̀ tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí àyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.
13 Olúwa sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la àfonífojì Sérádì kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá.
14 Ó gbà wá ní ọdún méjìdínlógójì (38) kí ó tó di wí pé a la àfonífojì Sérédì kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadesi Báníyà. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrin àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrin àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn.
15 Ọwọ́ Olúwa sì wà lára wọn fún ibi títí gbogbo wọn fi run tan nínú ibùdó.
16 Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátapáta nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú,
17 Olúwa sọ fún mi pé,
18 “Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbégbé Móábù kọjá ní Árì.
19 Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ámónì, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ámónì fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọ́tì ní ìní.”
20 (A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Réfáímù, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ámónì ń pè wọ́n ní Sámúsúmímù.
21 Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gògòrò bí àwọn ará Ánákì. Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ámónì, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.
22 Bákan náà ni Olúwa ṣe fún àwọn ọmọ Ísọ̀, tí wọ́n ń gbé ní Séírì, nígbà tí ó pa àwọn ará Hórì run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní.
23 Nípa ti àwọn ará Áfì, tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèkéé dé Gásà, àwọn ará Káfórì, tí wọ́n jáde láti Kírétè wá ni ó pa wọ́n run, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.)
24 “Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Ánónì. Kíyèsi, Mo ti fi Ṣíhónì ará Ámórì, ọba Héṣíbónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á.
25 Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdàmú ọkàn torí i ti yín.”
26 Mo rán àwọn ìránṣẹ́ sí Síhónì láti ihà Kédémótì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé,
27 “Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A ko ní yà sọ́tùn-ún tàbí sósì.
28 Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sáà jẹ́ kí a rìn kọjá:
29 gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Éṣáù tí ó ń gbé ní Séírì àti àwọn ará Móábù tí ó ń gbé ní Árì, ti gbà wá láàyè títí a fi la Jọ́dánì já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.”
30 Ṣùgbọ́n Ṣíhónì ọba Héṣíbónì kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.
31 Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsí i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”
32 Nígbà tí Síhónì àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jáhásì,
33 Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀.
34 Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátapáta tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí.
35 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa.
36 Láti Áróérì, létí odò Ánónì àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gílíádì, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa.
37 Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jábókù, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.