27 Ẹ fi ọrẹ síṣun yín kalẹ̀ lórí i pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, àti ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ ọrẹ yín ni ki ẹ dà sí pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ ẹran.
28 Ẹ kíyèsára láti máa gbọ́ràn sí gbogbo ìlànà tí mò ń fún un yín, kí o báà dára fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín nígbà gbogbo, nítorí pé nígbà náà ní ẹ tó ń ṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.
29 Olúwa Ọlọ́run yín yóò gé àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹ fẹ́ lé kúrò tí ẹ sì fẹ́ gba ilẹ̀ wọn kúrò níwájú u yín. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá tí lé wọn jáde tí ẹ sì ń gbé ilẹ̀ wọn.
30 Lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti pa wọ́n run níwájú u yín, ẹ sọ́ra kí ẹ má baà bọ́ sínú àdánwò nípa bíbéèrè nípa àwọn òrìṣà wọn wí pé, “Báwo ni àwọn orílẹ̀ èdè yìí ṣe ń sin àwọn òrìṣà wọn? Àwa náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀”
31 Ẹ má ṣe sin Olúwa Ọlọ́run yín bí àwọn, torí pé, nípa sínsin ọlọ́run wọn, wọ́n ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìríra tí Ọlọ́run kórìíra. Wọ́n ń dáná ṣun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti fi rúbọ sí ère òrìṣà wọn.
32 Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì se yọ kúró níbẹ̀.