1 Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀ta rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì, yóò wà pẹ̀lú rẹ.
2 Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá ṣíwájú, yóò sì bá ọmọ ogun sọ̀rọ̀,
3 yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀ta rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi àyè fún ìjayà níwájú u wọn.
4 Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ó ń lọ pẹ̀lú rẹ láti jà fún ọ kí ó sì fún ọ ní ìṣẹgun.”
5 Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé túntún tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú ṣójú ogun kí elòmìíràn sì gbà á.