13 Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, kórìíra rẹ̀,
14 tí o sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo sún mọ́ ọn. Èmi kò rí àmì ìbálé e rẹ̀.”
15 Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ìlú ní ẹnu bodè.
16 Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbààgbà, pé “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀.
17 Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúndíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fí aṣọ hàn níwájú àwọn àgbààgbà ìlú,
18 àwọn àgbààgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ́ ẹ́ níyà.
19 Wọn yóò sì gba ìtanràn ọgọ́rùn ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúndíá Ísírẹ́lì. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.