1 Mósè àti àwọn àgbà Isírẹ́lì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́.
2 Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì sí inú ilẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbékalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun.
3 Kí o kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí o bá ti ń ré kọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ.
4 Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ébálì, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun.
5 Kọ́ Pẹpẹ ṣíbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn.