6 Kí o kọ́ pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú òkúta nínú pápá kí o sì sun ẹbọ ni orí i rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.
7 Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
8 Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
9 Nígbà náà ni Móṣè àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, sọ fún Ísírẹ́lì pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí.
10 Gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
11 Ní ọjọ́ kan náà Móṣè pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.
12 Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gérísímù láti ṣúre fún àwọn ènìyàn: Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.