1 Bí o bá gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀ èdè ayé lọ.
2 Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sóríì rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ:
3 Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
4 Ìbùkún ni fún ọmọ inú ù rẹ, àti èṣo ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
5 Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ìpo ìyẹ̀fun rẹ.
6 Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí Ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.