13 Olúwa yóò fi ọ́ ṣe orí, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ìrù. Bí o bá fi etí sílẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ tí mo fi fún ọ kí o sì máa rọra tẹ̀lé wọn, ìwọ yóò máa wà lókè, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò wà ní ìsàlẹ̀ láé.
14 Má se yà sọ́tùn ún tàbí sósì kúrò, nínú èyíkéyìí àwọn àṣẹ tí mo fi fún ọ ní òní yìí, kí o má ṣe tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti máa sìn wọ́n.
15 Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sóríì rẹ yóò sì máa bá ọ lọ:
16 Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.
17 Ègún ni fún Agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.
18 Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èṣo ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
19 Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.