15 Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sóríì rẹ yóò sì máa bá ọ lọ:
16 Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.
17 Ègún ni fún Agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.
18 Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èṣo ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
19 Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
20 Olúwa yóò rán ègún sóríì rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀.
21 Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.