24 Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eekuru ẹ̀tù ìbọn yóò sì wá sílẹ̀ láti ojú ọ̀run títí tí yóò fi pa ọ́ run.
25 Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀ta rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò ṣá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé.
26 Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò.
27 Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Éjíbítì àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra.
28 Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.
29 Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ talẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.
30 Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èṣo rẹ.