45 Gbogbo ègun yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsí àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.
46 Wọn yóò jẹ́ àmì àti ìyanu fún ọ àti fún irú ọmọ rẹ títí láé.
47 Nítorí ìwọ kò sin Olúwa Ọlọ́run rẹ ní ayọ̀ àti inú dídùn ní àkókò àlàáfíà.
48 Nítorí náà nínú ebi àti òùngbẹ, nínú ìhòòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀ta à rẹ tí Olúwa rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.
49 Olúwa yóò mú àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ láti ọ̀nà jínjìn, bí òpin ayé, bí idì ti ń bẹ́ láti orí òkè sílẹ̀, orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè wọn.
50 Orílẹ̀ èdè tí ó rorò tí kò ní ojúrere fún àgbà tàbí àánú fún ọmọdé.
51 Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èṣo ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì túntún tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run.