57 ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí láti inú u rẹ̀ àti àwọn ọmọ tí ó ti bí. Nítorí ó fẹ́ láti jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀ nígbà ìgbógun tì àti ní ìgbà ìpọ́njú tí ọ̀ta rẹ yóò fi jẹ ọ́ nínú àwọn ìlú rẹ.
58 Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ,
59 Olúwa yóò rán ìyọnu tí ó ní ìbẹ̀rù sórí rẹ, àti sórí irú ọmọ ọ̀ rẹ, àti àwọn àjálù pípẹ́, àti ìmúna àti àìsàn ìlọ́ra.
60 Olúwa yóò mú gbogbo àrùn Éjíbítì tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá sórí ì rẹ, wọn yóò sì so mọ́ ọ.
61 Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ÌWÉ ÒFIN yìí wá sórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi run.
62 Ìwọ tí ó dàbí àìmòye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò sẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
63 Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.