58 Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ,
59 Olúwa yóò rán ìyọnu tí ó ní ìbẹ̀rù sórí rẹ, àti sórí irú ọmọ ọ̀ rẹ, àti àwọn àjálù pípẹ́, àti ìmúna àti àìsàn ìlọ́ra.
60 Olúwa yóò mú gbogbo àrùn Éjíbítì tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá sórí ì rẹ, wọn yóò sì so mọ́ ọ.
61 Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ÌWÉ ÒFIN yìí wá sórí ì rẹ, títí ìwọ yóò fi run.
62 Ìwọ tí ó dàbí àìmòye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò sẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
63 Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
64 Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.