15 Mo sì fi Gílíádì fún Mákírì,
16 ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti Gádì ni mo fún ní ilẹ̀ láti Gílíádì lọ dé odò Ánónì (àárin odò náà sì jẹ́ ààlà) títí ó fi dé odò Jábókù. Èyí tí i ṣe ààlà àwọn ará Ámónì.
17 Apá ìwọ̀ óòrùn rẹ̀ ni Jọ́dánì, ní aginjù, láti Kínérétì títí dé òkun aginjù (Tí í ṣe òkun iyọ̀) ní ihà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.
18 Mo pàṣẹ fún un yín ní ìgbà náà pé, “Olúwa Ọlọ́run yín ti fi ilẹ̀ yìí fún un yín láti ni ín. Ṣùgbọ́n, gbogbo àwọn ọkùnrin yín tí ó lera tí wọ́n sì ti dira ogun, gbọdọ̀ kọjá ṣíwájú àwọn arákùnrin yín: ará Ísírẹ́lì.
19 Àwọn ẹ̀yà a yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ohun ọ̀sìn in yín (Mo mọ̀ pé ẹ ti ní ohun ọ̀sìn púpọ̀) lè dúró ní àwọn ìlú tí mo fi fún un yín,
20 títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jọ́dánì. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”
21 Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Jósúà pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.