16 Nítorí mo pàṣẹ fún ọ lónìí láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, láti rìn ní ọ̀nà a rẹ̀ àti láti pa àwọn àṣẹ, ìpinnu àti òfin rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò máa gbé tí o ó sì máa pọ̀ sí i, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún ọ ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
17 Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n,
18 èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní-àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jọ́dánì láti gbà àti láti ní.
19 Lónìí mo pe ọ̀run àti ayé bí ẹlẹ́rìí sí ọ pé mo ti gbékalẹ̀ síwájú rẹ ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún. Nísinsìnyìí yan ìyè, nítorí kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè gbé
20 kí ìwọ sì lè fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, fetí sílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí Olúwa ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.