9 Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò mú ọ ṣe rere nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ, àti nínú gbogbo ọmọ inú ù rẹ, agbo ẹran ọ̀sìn rẹ àti èṣo ilẹ̀ rẹ. Olúwa yóò tún mú inú dídùn sínú ù rẹ yóò sì mú ọ ṣe déédé, gẹ́gẹ́ bí ó ti fi inú dídùn sínú àwọn baba rẹ.
10 Bí o bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.
11 Wàyí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un yín lónìí kò le jù fún un yín tàbí kọjá agbára yín.
12 Kò sí ní ọ̀run, tí ìwọ kò bá fi wí pé, “Ta ni yóò gòkè lọ sí ọ̀run fún wa, tí yóò sì mú wa fún wa, kí àwa lè gbọ́, kí a sì le ṣe é?”
13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ìhà kejì òkun, tí ìwọ ìbá fi wí pé, “Ta ni yóò rékọjá òkun lọ fún wa, tí yóò sì mú un wá fún wa, kí àwa lè gbọ́ ọ, kí a si le ṣe é?”
14 Kìí ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà súnmọ́ tòsí ì rẹ, ó wà ní ẹnu ù rẹ àti ní ọkàn rẹ kí ìwọ lè máa ṣe é.
15 Wòó mo gbé kalẹ̀ síwájú u yín lónìí, ìyè àti àlàáfíà, ikú àti ìparun.