19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítori ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ìn rẹ.
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú ù mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú un wọn.
21 Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun aṣán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀ èdè.
22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.
23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.
24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.
25 Idà ní òde,àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù.Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá,ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.