37 Yóò wí pé: “Òrìṣà a wọn dà báyìí,àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,
38 ọlọ́run tí ó jẹ ara ẹbọ wọntí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!
39 “Wòó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.
40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé:Èmi ti wà láàyè títí láé,
41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán miàti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá miÈmi kò sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.
42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:Ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,orí àwọn asáájú ọlá.”
43 Ẹyọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta a rẹ̀yóò sì se ètùtù fún ilẹ̀ rẹ̀ àti ènìyàn.