17 “Má ṣe pànìyàn.
18 “Má ṣe ṣe panṣágà.
19 “Má ṣe jalè.
20 “Má ṣe jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ
21 “Má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí aya aládúgbò rẹ, má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí ilé tàbí ilẹ̀ alábágbé rẹ, sí ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tàbí ohunkóhun tí í ṣe ti aládúgbò rẹ.”
22 Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ Olúwa tí a kéde rẹ̀ sí gbogbo ìpéjọpọ̀ ọ yín, níbẹ̀ ní orí òkè, láàrin iná, ìkùukù àti òkùnkùn biribiri: Kò sì fi ohunkóhun kún un mọ́. Ó sì kọ wọ́n sínú sílétì méjì, Ó sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́.
23 Nígbà tí ẹ gbóhùn láti inú òkùnkùn wá, nígbà tí iná náà ń yọná lala, àwọn aṣáájú ẹ̀yà a yín àti àwọn alàgbà a yín tọ̀ mí wá.